University of Lagos
Department of Linguistics, African & Asian Studies
YOR 310: O̝gbó̝n
Ìs̝èwádìí
olùkó̝: Ò̝mò̝wé
O̝ládiípò̝
Ajíbóyè
àkókò ìdánilé̝kò̝ó̝: Tuesday, 1-2pm and Wed 9-10am
o̝ó̝fíìsì A512 tel 0805-174-0201
àkóónú
is̝é̝: Lárijà is̝é̝ yìí ni láti s̝e àlàkalè̝ orís̝irís̝i o̝gbó̝n àti ète tí
a máa n lò s̝e is̝é̝ ìwádìí aje̝-mó̝-akadá. A ó wo ohun tí a n pè ni is̝é̝-ìwádìí. Ìmúrasílè̝ láti lo̝ sí oko ìwádìí àti sís̝a èròjà ìwádìí jo̝. A ó tún wo bí a ti máa n s̝e àko̝sílè̝ àbáde is̝é̝-ìwádìí pè̝lú ò̝nà tí a gbà máa n s̝e ìtúpalè̝ èròjà
ìwádìí
sílábó̝ò̝sì
1 Kí ni is̝é̝-ìwádìí àti o̝gbó̝n ìs̝èwádìí
2 Yíyan
kókó orí ò̝rò̝ fún ìwádìí
3 Ìgbáradì
s̝áájú lílo̝ Oko Ìwádìí
a.
Àkójo̝ èdè fáyè̝wò
b.
Àtòjo̝ ìbéèrè fún is̝é̝ ìwádìí
4 Ìmúrasílè̝ fún oko ìwádìí
5 Orís̝irís̝i ìwò̝n àti irins̝é̝ ìwádìí
6 Ìsòro
tí ó máa n dojúko̝ as̝èwádìí
7 S̝ís̝e àko̝sílè̝ is̝é̝-ìwádìí
a.
Àfihàn orí ò̝rò̝ fún is̝é̝ ìwádìí
b.
Àyo̝lò àti àko̝sílè̝ rè̝
b. Kíka àwo̝n is̝é̝ tó ní àsomó̝ pè̝lú orí ò̝rò̝
d. Àfihàn tíó̝rì̝ tí a ó fi s̝e ìtúpalè̝
Ohun àìgbó̝dò̝más̝e
1. Pépà àpilé̝ko̝ lórí orí-ò̝rò̝ fún is̝é̝ ìwádìí tí aké̝kò̝ó̝ bá yàn láàyò
2. Ìdánwò ránpé̝
Àwo̝n ìwé-àkànlò
1. Dúró Adélékè àti Ké̝mi Adébíyí (2003). O̝gbó̝n
Ìs̝èwádìí
ní Èdè Yorùbá
2. Adéye̝mí, Lérè. (2006). Tíó̝rì
Lítírés̝ò̝
ní Èdè Yorùbá.
3. Ayo Bamgbose (ed.). 1984. Yoruba Metalanguage (Èdè-Ìperí Yorùbá). Volume 1.
4. Oladele Awobuluyi (ed.). 1990. Yoruba Metalanguage (Èdè-Ìperí Yorùbá)
Volume 2.
No comments:
Post a Comment